Deu 22:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ kò gbọdọ ri akọ-malu tabi agutan arakunrin rẹ ti o nṣako, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn; bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o mú wọn pada tọ̀ arakunrin rẹ wá.

2. Bi arakunrin rẹ kò ba si sí nitosi rẹ, tabi bi iwọ kò ba mọ̀ ọ, njẹ ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ, ki o si wà lọdọ rẹ titi arakunrin rẹ yio fi wá a wá, ki iwọ ki o si fun u pada.

3. Bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o si ṣe si gbogbo ohun ninù arakunrin rẹ, ti o nù lọwọ rẹ̀, ti iwọ si ri: ki iwọ ki o máṣe mú oju rẹ kuro.

4. Iwọ kò gbọdọ ri kẹtẹkẹtẹ tabi akọ-malu arakunrin rẹ ki o ṣubu li ọ̀na, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn: iwọ o si ràn a lọwọ nitõtọ lati gbé e dide.

5. Obinrin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ̀, bẹ̃li ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obinrin wọ̀: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bẹ̃ irira ni nwọn si OLUWA Ọlọrun rẹ.

6. Bi iwọ ba bá itẹ́ ẹiyẹ kan pade lori igi kan, tabi ni ilẹ, ti o ní ọmọ tabi ẹyin, ti iya si bà lé ọmọ tabi lé ẹyin na, iwọ kò gbọdọ kó iya pẹlu ọmọ:

7. Bikoṣe ki iwọ ki o jọwọ iya lọwọ lọ, ki iwọ ki o si kó ọmọ fun ara rẹ; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ.

8. Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu.

9. Iwọ kò gbọdọ fi irú meji irugbìn gbìn ọgbà-àjara rẹ; ki eso irugbìn rẹ gbogbo ti iwọ ti gbìn, ati asunkún ọgbà-àjara rẹ, ki o má ba di ti Ọlọrun.

10. Iwọ kò gbọdọ fi akọ-malu ati kẹtẹkẹtẹ tulẹ pọ̀.

Deu 22