Deu 21:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ki o si bọ́ aṣọ igbẹsin rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ki o si joko ninu ile rẹ, ki o sọkun baba rẹ̀, ati iya rẹ̀ li oṣù kan tọ̀tọ: lẹhin ìgba na ki iwọ ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ma ṣe ọkọ rẹ̀, on a si ma ṣe aya rẹ.

14. Bi o ba si ṣe, ti on kò ba wù ọ, njẹ ki iwọ ki o jẹ ki o ma lọ si ibi ti o fẹ́; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ tà a rára li owo, iwọ kò gbọdọ lò o bi ẹrú, nitoriti iwọ ti tẹ́ ẹ logo.

15. Bi ọkunrin kan ba si lí aya meji, ti o fẹ́ ọkan ti o si korira ekeji, ti nwọn si bi ọmọ fun u, ati eyiti o fẹ́ ati eyiti o korira; bi akọ́bi ọmọ na ba ṣe ti ẹniti o korira;

16. Yio si ṣe, li ọjọ́ ti o ba fi awọn ọmọ rẹ̀ jogún ohun ti o ní, ki o máṣe fi ọmọ obinrin ti o fẹ́ ṣe akọ́bi ni ipò ọmọ obinrin ti o korira, ti iṣe akọ́bi:

17. Ṣugbọn ki o jẹwọ ọmọ obinrin ti o korira li akọ́bi, ni fifi ipín meji fun u ninu ohun gbogbo ti o ní: nitoripe on ni ipilẹṣẹ agbara rẹ̀; itọsi akọ́bi ni tirẹ̀.

18. Bi ọkunrin kan ba lí ọmọkunrin kan ti o ṣe agídi ati alaigbọran, ti kò gbà ohùn baba rẹ̀ gbọ́, tabi ohùn iya rẹ̀, ati ti nwọn nà a, ti kò si fẹ́ gbà tiwọn gbọ́:

19. Nigbana ni ki baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ki o mú u, ki nwọn ki o si fà a jade tọ̀ awọn àgba ilu rẹ̀ wá ati si ibode ibujoko rẹ̀;

20. Ki nwọn ki o si wi fun awọn àgba ilu rẹ̀ pe, Ọmọ wa yi, alagídi ati alaigbọran ni, on kò fẹ́ gbọ́ ohùn wa; ọjẹun ati ọmuti ni.

21. Ki gbogbo awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-ibi kuro lãrin nyin; gbogbo Israeli a si gbọ́, nwọn a si bẹ̀ru.

22. Bi ọkunrin kan ba dá ẹ̀ṣẹ kan ti o yẹ si ikú, ti a si pa a, ti iwọ si so o lori igi;

23. Ki okú rẹ̀ ki o máṣe gbé ori igi ni gbogbo oru, ṣugbọn bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o sin i li ọjọ́ na; nitoripe ẹni egún Ọlọrun li ẹniti a so; ki iwọ ki o má ba bà ilẹ rẹ jẹ́, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.

Deu 21