8. Ati bi OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, ti on ti bura fun awọn baba rẹ, ti o sì fun ọ ni gbogbo ilẹ na, ti o si ṣe ileri fun awọn baba rẹ;
9. Bi iwọ ba pa gbogbo ofin yi mọ́ lati ma ṣe e, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati lati ma rìn titi li ọ̀na rẹ̀; nigbana ni ki iwọ ki o fi ilu mẹta kún u si i fun ara rẹ, pẹlu mẹta wọnyi;
10. Ki a má ba tà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ninu ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki ẹ̀jẹ ki o má ba wà li ọrùn rẹ.
11. Ṣugbọn bi ọkunrin kan ba korira ẹnikeji rẹ̀, ti o si ba dè e, ti o si dide si i, ti o si lù u li alupa, ti o si kú, ti on si salọ sinu ọkan ninu ilu wọnyi:
12. Njẹ ki awọn àgba ilu rẹ̀ ki o ránni ki nwọn ki o si mú u ti ibẹ̀ wá, ki nwọn ki o si fà a lé agbẹsan ẹ̀jẹ lọwọ ki o ba le kú.
13. Ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u, ṣugbọn ki iwọ ki o mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lori Israeli, ki o si le dara fun ọ.
14. Iwọ kò gbọdọ yẹ̀ àla ẹnikeji rẹ, ti awọn ara iṣaju ti pa ni ilẹ iní rẹ ti iwọ o ní, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.
15. Ki ẹlẹri kanṣoṣo ki o máṣe dide jẹri tì enia nitori aiṣedede kan, tabi nitori ẹ̀ṣẹ kan ninu ẹ̀ṣẹ ti o ba ṣẹ̀: li ẹnu ẹlẹri meji, tabi li ẹnu ẹlẹri mẹta, li ọ̀ran yio fẹsẹmulẹ.
16. Bi ẹlẹri eké ba dide si ọkunrin lati jẹri tì i li ohun ti kò tọ́:
17. Njẹ ki awọn ọkunrin mejeji na lãrin ẹniti ọ̀rọ iyàn na gbé wà, ki o duro niwaju OLUWA, niwaju awọn alufa ati awọn onidajọ, ti yio wà li ọjọ wọnni,
18. Ki awọn onidajọ na ki o si tọ̀sẹ rẹ̀ pẹlẹpẹlẹ: si kiyesi i bi ẹlẹri na ba ṣe ẹlẹri eké, ti o si jẹri-eké si arakunrin rẹ̀;
19. Njẹ ki ẹnyin ki o ṣe si i, bi on ti rò lati ṣe si arakunrin rẹ̀: bẹ̃ni iwọ o si mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
20. Awọn ti o kù yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù irú ìwa-buburu bẹ̃ mọ́ lãrin nyin.
21. Ki oju rẹ ki o má si ṣe ṣãnu; ẹmi fun ẹmi, oju fun oju, ehín fun ehín, ọwọ́ fun ọwọ́, ẹsẹ̀ fun ẹsẹ̀.