Deu 19:1-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro, ilẹ ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilu wọn, ati ni ile wọn;

2. Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ lãrin ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.

3. Ki iwọ ki o là ọ̀na kan fun ara rẹ, ki iwọ ki o si pín àgbegbe ilẹ rẹ si ipa mẹta, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní, ki gbogbo apania ki o ma sá sibẹ̀.

4. Eyi si ni ọ̀ran apania, ti yio ma sá sibẹ̀, ki o le yè: ẹnikẹni ti o ba ṣeṣi pa ẹnikeji rẹ̀, ti on kò korira rẹ̀ tẹlẹrí;

5. Bi nigbati enia ba wọ̀ inu igbó lọ pélu ẹnikeji rẹ̀ lati ke igi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ gbé ãke lati fi ke igi na lulẹ, ti ãke si yọ kuro ninu erú, ti o si bà ẹnikeji rẹ̀, ti on kú; ki o salọ si ọkan ninu ilu wọnni, ki o si yè:

6. Ki agbẹsan ẹ̀jẹ ki o má ba lepa apania na, nigbati ọkàn rẹ̀ gboná, ki o si lé e bá, nitoriti ọ̀na na jìn, a si pa a; nigbati o jẹ pe kò yẹ lati kú, niwọnbi on kò ti korira rẹ̀ tẹlẹrí.

7. Nitorina emi fi aṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ.

8. Ati bi OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, ti on ti bura fun awọn baba rẹ, ti o sì fun ọ ni gbogbo ilẹ na, ti o si ṣe ileri fun awọn baba rẹ;

9. Bi iwọ ba pa gbogbo ofin yi mọ́ lati ma ṣe e, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati lati ma rìn titi li ọ̀na rẹ̀; nigbana ni ki iwọ ki o fi ilu mẹta kún u si i fun ara rẹ, pẹlu mẹta wọnyi;

10. Ki a má ba tà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ninu ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki ẹ̀jẹ ki o má ba wà li ọrùn rẹ.

11. Ṣugbọn bi ọkunrin kan ba korira ẹnikeji rẹ̀, ti o si ba dè e, ti o si dide si i, ti o si lù u li alupa, ti o si kú, ti on si salọ sinu ọkan ninu ilu wọnyi:

12. Njẹ ki awọn àgba ilu rẹ̀ ki o ránni ki nwọn ki o si mú u ti ibẹ̀ wá, ki nwọn ki o si fà a lé agbẹsan ẹ̀jẹ lọwọ ki o ba le kú.

13. Ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u, ṣugbọn ki iwọ ki o mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lori Israeli, ki o si le dara fun ọ.

14. Iwọ kò gbọdọ yẹ̀ àla ẹnikeji rẹ, ti awọn ara iṣaju ti pa ni ilẹ iní rẹ ti iwọ o ní, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.

15. Ki ẹlẹri kanṣoṣo ki o máṣe dide jẹri tì enia nitori aiṣedede kan, tabi nitori ẹ̀ṣẹ kan ninu ẹ̀ṣẹ ti o ba ṣẹ̀: li ẹnu ẹlẹri meji, tabi li ẹnu ẹlẹri mẹta, li ọ̀ran yio fẹsẹmulẹ.

16. Bi ẹlẹri eké ba dide si ọkunrin lati jẹri tì i li ohun ti kò tọ́:

Deu 19