Deu 18:16-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú.

17. OLUWA si wi fun mi pe, Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ.

18. Emi o gbé wolĩ kan dide fun wọn lãrin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọ̀rọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ.

19. Yio si ṣe, ẹniti kò ba fetisi ọ̀rọ mi ti on o ma sọ li orukọ mi, emi o bère lọwọ rẹ̀.

Deu 18