Deu 18:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ.

2. Nitorina ni nwọn ki yio ṣe ni iní lãrin awọn arakunrin wọn: OLUWA ni iní wọn, bi o ti wi fun wọn.

3. Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo.

4. Akọ́so ọkà rẹ pẹlu, ati ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́rẹ irun agutan rẹ, ni ki iwọ ki o fi fun u.

5. Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ li o yàn a ninu gbogbo awọn ẹ̀ya rẹ, lati ma duro ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai.

6. Ati bi ọmọ Lefi kan ba ti inu ibode rẹ kan wá, ni gbogbo Israeli, nibiti o gbé nṣe atipo, ti o si fi gbogbo ifẹ́ inu rẹ̀ wá si ibi ti OLUWA yio yàn;

7. Njẹ ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin li orukọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, bi gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Lefi, ti nduro nibẹ̀ niwaju OLUWA.

8. Ipín kanna ni ki nwọn ki o ma jẹ, làika eyiti o ní nipa tità ogún baba rẹ̀.

9. Nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe kọ́ ati ṣe gẹgẹ bi ìwa-irira awọn orilẹ-ède wọnni.

10. Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́,

11. Tabi atuju, tabi aba-iwin-gbìmọ, tabi oṣó, tabi abokulò.

12. Nitoripe gbogbo awọn ti nṣe nkan wọnyi irira ni si OLUWA: ati nitori irira wọnyi ni OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe lé wọn jade kuro niwaju rẹ.

13. Ki iwọ ki o pé lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ.

Deu 18