5. Nigbana ni ki iwọ ki o mú ọkunrin tabi obinrin na, ti o ṣe ohun buburu yi jade wá, si ibode rẹ, ani ọkunrin tabi obinrin na, ki iwọ ki o si sọ wọn li okuta pa.
6. Li ẹnu ẹlẹri meji, tabi ẹlẹri mẹta, li a o pa ẹniti o yẹ si ikú; ṣugbọn li ẹnu ẹlẹri kan, a ki yio pa a.
7. Ọwọ́ awọn ẹlẹri ni yio tète wà lara rẹ̀ lati pa a, lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia. Bẹ̃ni iwọ o si mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.
8. Bi ẹjọ́ kan ba ṣoro jù fun ọ lati dá, lãrin èjẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ọ̀ran on ọ̀ran, ati lãrin ìluni ati ìluni, ti iṣe ọ̀ran iyàn ninu ibode rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o dide, ki o si gòke lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn;
9. Ki iwọ ki o si tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi lọ, ati onidajọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni: ki o si bère; nwọn o si fi ọ̀rọ idajọ hàn ọ:
10. Ki iwọ ki o si ṣe bi ọ̀rọ idajọ, ti awọn ará ibi ti OLUWA yio yàn na yio fi hàn ọ; ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti nwọn kọ́ ọ:
11. Gẹgẹ bi ọ̀rọ ofin ti nwọn o kọ́ ọ, ati gẹgẹ bi idajọ ti nwọn o wi fun ọ, ni ki iwọ ki o ṣe: ki iwọ ki o máṣe yà si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi, kuro li ọ̀rọ ti nwọn o fi hàn ọ.
12. Ọkunrin na ti o ba si fi igberaga ṣe e, ti kò fẹ́ gbọ́ ti alufa na, ti o duro lati ma ṣe iṣẹ alufa nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, tabi lati gbọ́ ti onidajọ na, ani ọkunrin na yio kú: iwọ o si mú ìwabuburu kuro ni Israeli.
13. Gbogbo enia yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki yio si gberaga mọ́.