Deu 17:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ kò gbọdọ fi akọmalu, tabi agutan, ti o lí àbuku, tabi ohun buburu kan rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ.

2. Bi a ba ri lãrin nyin, ninu ibode rẹ kan ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ọkunrin tabi obinrin ti nṣe nkan buburu li oju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni rire majẹmu rẹ̀ kọja,

3. Ti o si lọ ti o nsìn ọlọrun miran, ti o si mbọ wọn, iba ṣe õrùn, tabi oṣupa, tabi ọkan ninu ogun ọrun, ti emi kò palaṣẹ;

4. Ti a ba si wi fun ọ, ti iwọ si ti gbọ́, ti iwọ si wádi rẹ̀ rere, si kiyesi i, ti o jasi otitọ, ti ohun na si daniloju pe, a ṣe irú irira yi ni Israeli;

5. Nigbana ni ki iwọ ki o mú ọkunrin tabi obinrin na, ti o ṣe ohun buburu yi jade wá, si ibode rẹ, ani ọkunrin tabi obinrin na, ki iwọ ki o si sọ wọn li okuta pa.

6. Li ẹnu ẹlẹri meji, tabi ẹlẹri mẹta, li a o pa ẹniti o yẹ si ikú; ṣugbọn li ẹnu ẹlẹri kan, a ki yio pa a.

7. Ọwọ́ awọn ẹlẹri ni yio tète wà lara rẹ̀ lati pa a, lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia. Bẹ̃ni iwọ o si mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.

8. Bi ẹjọ́ kan ba ṣoro jù fun ọ lati dá, lãrin èjẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ọ̀ran on ọ̀ran, ati lãrin ìluni ati ìluni, ti iṣe ọ̀ran iyàn ninu ibode rẹ, nigbana ni ki iwọ ki o dide, ki o si gòke lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn;

9. Ki iwọ ki o si tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi lọ, ati onidajọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni: ki o si bère; nwọn o si fi ọ̀rọ idajọ hàn ọ:

10. Ki iwọ ki o si ṣe bi ọ̀rọ idajọ, ti awọn ará ibi ti OLUWA yio yàn na yio fi hàn ọ; ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ma ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti nwọn kọ́ ọ:

11. Gẹgẹ bi ọ̀rọ ofin ti nwọn o kọ́ ọ, ati gẹgẹ bi idajọ ti nwọn o wi fun ọ, ni ki iwọ ki o ṣe: ki iwọ ki o máṣe yà si ọwọ́ ọtún, tabi si òsi, kuro li ọ̀rọ ti nwọn o fi hàn ọ.

12. Ọkunrin na ti o ba si fi igberaga ṣe e, ti kò fẹ́ gbọ́ ti alufa na, ti o duro lati ma ṣe iṣẹ alufa nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, tabi lati gbọ́ ti onidajọ na, ani ọkunrin na yio kú: iwọ o si mú ìwabuburu kuro ni Israeli.

13. Gbogbo enia yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki yio si gberaga mọ́.

Deu 17