10. Ki iwọ ki o si pa ajọ ọ̀sẹ mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu ọrẹ ifẹ́-atinuwa ọwọ́ rẹ, ti iwọ o fi fun u, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti busi i fun ọ:
11. Ki iwọ ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ lãrin rẹ, ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si.
12. Ki iwọ ki o si ma ranti pe, ẹrú ni iwọ ti jẹ́ ni Egipti: ki iwọ ki o si ma kiyesi ati ṣe ìlana wọnyi.
13. Ki iwọ ki o si ma pa ajọ agọ́ mọ́ li ọjọ́ meje, lẹhin ìgba ti iwọ ba ṣe ipalẹmọ ilẹ-ipakà rẹ ati ibi-ifunti rẹ.
14. Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ajọ rẹ, iwọ, ati ọmọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ ọkunrin, ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, ati ọmọ Lefi, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ.
15. Ijọ́ meje ni ki iwọ ki o fi ṣe ajọ si OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi ti OLUWA yio yàn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo asunkún rẹ, ati ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ, nitorina ki iwọ ki o ma yọ̀ nitõtọ.
16. Lẹ̃mẹta li ọdún ni ki gbogbo awọn ọkunrin rẹ ki o farahàn niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn; ni ajọ àkara alaiwu, ati ni ajọ ọ̀sẹ, ati ni ajọ agọ́: ki nwọn ki o má si ṣe ṣánwọ wá iwaju OLUWA:
17. Ki olukuluku ki o mú ọrẹ wá bi agbara rẹ̀ ti to, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ.
18. Awọn onidajọ ati awọn ijoye ni ki iwọ ki o fi jẹ ninu ibode rẹ gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, gẹgẹ bi ẹ̀ya rẹ: ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia na li ododo.
19. Iwọ kò gbọdọ lọ́ idajọ; iwọ kò gbọdọ ṣe ojuṣaju enia: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbà ẹ̀bun; nitoripe ẹ̀bun ni ifọ́ ọlọgbọ́n li oju, on a si yi ọ̀rọ olododo po.
20. Eyiti iṣe ododo patapata ni ki iwọ ki o ma tọ̀ lẹhin, ki iwọ ki o le yè, ki iwọ ki o si ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
21. Iwọ kò gbọdọ rì igi oriṣa kan sunmọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ o mọ fun ara rẹ.
22. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbé ọwọ̀n kan kalẹ fun ara rẹ: ti OLUWA Ọlọrun rẹ korira.