1. IWỌ ma kiyesi oṣù Abibu, ki o si ma pa ajọ irekọja mọ́ si OLUWA Ọlọrun rẹ: nitoripe li oṣù Abibu ni OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ lati ilẹ Egipti jade wa li oru.
2. Nitorina ki iwọ ki o ma pa ẹran irekọja si OLUWA Ọlọrun rẹ, ninu agbo-ẹran ati ninu ọwọ́-ẹran, ni ibi ti OLUWA yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.
3. Iwọ kò gbọdọ jẹ àkara wiwu pẹlu rẹ̀; ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu pẹlu rẹ̀, ani onjẹ ipọnju; nitoripe iwọ ti ilẹ Egipti jade wá ni kanjukanju: ki iwọ ki o le ma ranti ọjọ́ ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wa, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo.
4. Ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ li àgbegbe rẹ gbogbo ni ijọ́ meje; bẹ̃ni ki ohun kan ninu ẹran ti iwọ o fi rubọ li ọjọ́ kini li aṣalẹ, ki o máṣe kù di owurọ̀.
5. Ki iwọ ki o máṣe pa ẹran irekọja na ninu ibode rẹ kan, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ:
6. Ṣugbọn bikoṣe ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o pa ẹran irekọja na li aṣalẹ, nigba ìwọ-õrùn, li akokò ti iwọ ti ilẹ Egipti jade wá.
7. Ki iwọ ki o si sun u, ki iwọ ki o si jẹ ẹ ni ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn: ki iwọ ki o si pada li owurọ̀, ki o si lọ sinu agọ́ rẹ.