15. Ki iwọ ki o si ranti pe, iwọ a ti ma ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ: nitorina ni mo ṣe fi aṣẹ nkan yi lelẹ fun ọ li oni.
16. Yio si ṣe, bi o ba wi fun ọ pe, Emi ki yio jade lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o fẹ́ ọ ati ile rẹ, nitoriti o dara fun u lọdọ rẹ;
17. Nigbana ni ki iwọ ki o mú olu kan, ki iwọ ki o si fi lu u li etí mọ́ ara ilẹkun, ki on ki o si ma ṣe ọmọ-ọdọ rẹ lailai. Ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ni ki iwọ ki o ṣe bẹ̃ si gẹgẹ.
18. Ki o máṣe ro ọ loju, nigbati iwọ ba rán a li ominira lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o ní iye lori to alagbaṣe meji ni sísìn ti o sìn ọ li ọdún mẹfa: OLUWA Ọlọrun rẹ yio si busi i fun ọ ninu gbogbo ohun ti iwọ nṣe.
19. Gbogbo akọ́bi akọ ti o ti inu ọwọ-ẹran rẹ ati inu agbo-eran rẹ wá, ni ki iwọ ki o yàsi-mimọ́, fun OLUWA Ọlọrun rẹ: iwọ kò gbọdọ fi akọ́bi ninu akọmalu rẹ ṣe iṣẹ kan, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹrun akọ́bi agutan rẹ,
20. Ki iwọ ki o ma jẹ ẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ọdọdún, ni ibi ti OLUWA yio yàn, iwọ, ati awọn ara ile rẹ.