10. Ki iwọ ki o fi fun u nitõtọ, ki inu rẹ ki o máṣe bàjẹ́ nigbati iwọ ba fi fun u: nitoripe nitori nkan yi ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ ni gbogbo iṣẹ rẹ, ati ni gbogbo ohun ti iwọ ba dá ọwọ́ rẹ lé.
11. Nitoripe talakà kò le tán ni ilẹ na: nitorina ni mo ṣe paṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun arakunrin rẹ, fun talakà rẹ, ati fun alainí rẹ, ninu ilẹ rẹ.
12. Ati bi a ba tà arakunrin rẹ kan fun ọ, ọkunrin Heberu, tabi obinrin Heberu, ti o si sìn ọ li ọdún mẹfa; njẹ li ọdún keje ki iwọ ki o rán a lọ kuro lọdọ rẹ li ominira.
13. Nigbati iwọ ba si nrán a lọ li ominira kuro lọdọ rẹ, iwọ kò gbọdọ jẹ ki o lọ li ọwọ́ ofo:
14. Ki iwọ ki o pèse fun u li ọ̀pọlọpọ lati inu agbo-ẹran rẹ wá, ati lati ilẹ-ipakà rẹ, ati lati ibi ifunti rẹ, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún ọ ni ki iwọ ki o fi fun u.
15. Ki iwọ ki o si ranti pe, iwọ a ti ma ṣe ẹrú ni ilẹ Egipti, ati pe OLUWA Ọlọrun rẹ si gbà ọ silẹ: nitorina ni mo ṣe fi aṣẹ nkan yi lelẹ fun ọ li oni.
16. Yio si ṣe, bi o ba wi fun ọ pe, Emi ki yio jade lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o fẹ́ ọ ati ile rẹ, nitoriti o dara fun u lọdọ rẹ;
17. Nigbana ni ki iwọ ki o mú olu kan, ki iwọ ki o si fi lu u li etí mọ́ ara ilẹkun, ki on ki o si ma ṣe ọmọ-ọdọ rẹ lailai. Ati ọmọ-ọdọ rẹ obinrin ni ki iwọ ki o ṣe bẹ̃ si gẹgẹ.
18. Ki o máṣe ro ọ loju, nigbati iwọ ba rán a li ominira lọ kuro lọdọ rẹ; nitoriti o ní iye lori to alagbaṣe meji ni sísìn ti o sìn ọ li ọdún mẹfa: OLUWA Ọlọrun rẹ yio si busi i fun ọ ninu gbogbo ohun ti iwọ nṣe.
19. Gbogbo akọ́bi akọ ti o ti inu ọwọ-ẹran rẹ ati inu agbo-eran rẹ wá, ni ki iwọ ki o yàsi-mimọ́, fun OLUWA Ọlọrun rẹ: iwọ kò gbọdọ fi akọ́bi ninu akọmalu rẹ ṣe iṣẹ kan, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ rẹrun akọ́bi agutan rẹ,
20. Ki iwọ ki o ma jẹ ẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ọdọdún, ni ibi ti OLUWA yio yàn, iwọ, ati awọn ara ile rẹ.
21. Bi abùku kan ba si wà lara rẹ̀, bi o mukun ni, bi o fọju ni, tabi bi o ni abùku buburu kan, ki iwọ ki o máṣe fi rubọ si OLUWA Ọlọrun rẹ.
22. Ki iwọ ki o jẹ ẹ ninu ibode rẹ: alaimọ́ ati ẹni ti o mọ́ ni ki o jẹ ẹ bakanna, bi esuwo, ati bi agbọnrin.
23. Kìki iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ rẹ̀; ki iwọ ki o dà a silẹ bi omi.