1. ỌMỌ OLUWA Ọlọrun nyin li ẹnyin iṣe: ẹnyin kò gbọdọ̀ bù ara nyin li abẹ, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fá iwaju nyin nitori okú.
2. Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, OLUWA si ti yàn ọ lati ma ṣe enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo orilẹ-ède lọ ti mbẹ lori ilẹ.
3. Iwọ kò gbọdọ jẹ ohun irira kan.
4. Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ: akọmalu, agutan, ati ewurẹ,
5. Agbọnrin, ati esuwo, ati gala, ati ewurẹ igbẹ́, ati pigargi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu.
6. Ati gbogbo ẹranko ti o là bàta-ẹsẹ̀, ti o si pinyà bàta-ẹsẹ̀ si meji, ti o si njẹ apọjẹ ninu ẹranko, eyinì ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
7. Ṣugbọn wọnyi ni ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi ninu awọn ti o là bàta-ẹsẹ̀; bi ibakasiẹ, ati ehoro, ati garà, nitoriti nwọn njẹ apọjẹ ṣugbọn nwọn kò là bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ ni nwọn jasi fun nyin:
8. Ati ẹlẹdẹ̀, nitoriti o là bàta-ẹsẹ̀ ṣugbọn kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ ni fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn okú wọn.
9. Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo eyiti mbẹ ninu omi: gbogbo eyiti o ní lẹbẹ ti o si ní ipẹ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
10. Ati ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ti kò si ní ipẹ́, ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ẹ; alaimọ́ ni fun nyin.
11. Gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
12. Ṣugbọn wọnyi li awọn ti ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu wọn: idì, ati aṣa-idì, ati idì-ẹja.
13. Ati glede, ati aṣá, ati gunugun li onirũru rẹ̀;
14. Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀;
15. Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀;
16. Owiwi kekere, ati owiwi nla, ati ogbugbu;
17. Ati pelikan, ati àkala, ati ìgo;
18. Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán.
19. Ati ohun gbogbo ti nrakò ti nfò, o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: a kò gbọdọ jẹ wọn.
20. Ṣugbọn gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.