Deu 13:6-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Bi arakunrin rẹ, ọmọ iya rẹ, tabi ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ obinrin, tabi aya õkan-àiya rẹ, tabi ọrẹ́ rẹ, ti o dabi ọkàn ara rẹ, bi o ba tàn ọ ni ìkọkọ, wipe, Jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti iwọ kò mọ̀ rí, iwọ, tabi awọn baba rẹ;

7. Ninu awọn oriṣa awọn enia ti o yi nyin kakiri, ti o sunmọ ọ, tabi ti o jìna si ọ, lati opin ilẹ dé opin ilẹ;

8. Iwọ kò gbọdọ jẹ fun u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fetisi tirẹ̀; bẹ̃ni ki oju ki o máṣe ro ọ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe da a si, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe bò o:

9. Ṣugbọn pipa ni ki o pa a; ọwọ́ rẹ ni yio kọ́ wà lara rẹ̀ lati pa a, ati lẹhin na ọwọ́ gbogbo enia.

10. Ki iwọ ki o si sọ ọ li okuta, ki o kú; nitoriti o nwá ọ̀na lati tì ọ kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú.

11. Gbogbo Israeli yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù ìwabuburu bi irú eyi mọ́ lãrin nyin.

12. Bi iwọ ba gbọ́ ninu ọkan ninu awọn ilu rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ma gbé inu rẹ̀ pe,

13. Awọn ọkunrin kan, awọn ọmọ Beliali, nwọn jade lọ kuro ninu nyin, nwọn si kó awọn ara ilu wọn sẹhin, wipe, Ẹ jẹ ki a lọ ki a ma sìn ọlọrun miran, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.

14. Nigbana ni ki iwọ ki o bère, ki iwọ ki o si ṣe àwari, ki o si bère pẹlẹpẹlẹ; si kiyesi i, bi o ba ṣe otitọ, ti ohun na ba si da nyin loju, pe a ṣe irú nkan irira bẹ̃ ninu nyin;

15. Ki iwọ ki o fi oju idà kọlù awọn ara ilu na nitõtọ, lati run u patapata, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ohunọ̀sin inu rẹ̀, ni ki iwọ ki o fi oju idà pa.

16. Ki iwọ ki o si kó gbogbo ikogun rẹ̀ si ãrin igboro rẹ̀, ki iwọ ki o si fi iná kun ilu na, ati gbogbo ikogun rẹ̀ patapata fun OLUWA Ọlọrun rẹ: ki o si ma jasi òkiti lailai; a ki yio si tun tẹ̀ ẹ dó mọ́.

17. Ki ọkan ninu ohun ìyasọtọ na má si ṣe mọ́ ọ lọwọ; ki OLUWA ki o le yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀, ki o si ma ṣãnu fun ọ, ki o si ma ṣe iyọnu rẹ, ki o si ma mu ọ bisi i, bi o ti bura fun awọn baba rẹ;

18. Nigbati iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ofin rẹ̀ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.

Deu 13