1. BI wolĩ kan ba hù lãrin rẹ, tabi alalá kan, ti o si fi àmi tabi iṣẹ́-iyanu kan hàn ọ,
2. Ti àmi na tabi iṣẹ-iyanu na ti o sọ fun ọ ba ṣẹ, wipe, Ẹ jẹ ki a tẹlé ọlọrun miran lẹhin, ti iwọ kò ti mọ̀ rí, ki a si ma sìn wọn;
3. Iwọ kò gbọdọ fetisi ọ̀rọ wolĩ na, tabi alalá na: nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ndan nyin wò ni, lati mọ̀ bi ẹnyin ba fi gbogbo àiya nyin, ati gbogbo ọkàn nyin fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin.
4. Lẹhin OLUWA Ọlọrun nyin ni ki ẹnyin ki o ma rìn, on ni ki ẹ si ma bẹ̀ru, ki ẹ si ma pa ofin rẹ̀ mọ́, ki ẹ si ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ki ẹ si ma sìn i, ki ẹ si ma faramọ́ ọ.