Deu 12:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA.

12. Ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin, ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode nyin, nitori on kò ní ipín tabi iní pẹlu nyin.

13. Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe ru ẹbọ sisun rẹ ni ibi gbogbo ti iwọ ba ri:

14. Bikoṣe ni ibi ti OLUWA yio yàn ninu ọkan ninu awọn ẹ̀ya rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ.

15. Ṣugbọn ki iwọ ki o ma pa, ki o si ma jẹ ẹran ninu ibode rẹ gbogbo, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ ni ki o ma jẹ ninu rẹ̀, bi esuro, ati bi agbọnrin.

16. Kìki ẹ̀jẹ li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; lori ilẹ ni ki ẹ dà a si bi omi.

17. Ki iwọ ki o máṣe jẹ idamẹwa ọkà rẹ ninu ibode rẹ, tabi ti ọti-waini rẹ, tabi ti oróro rẹ, tabi ti akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, tabi ti agbo-ẹran rẹ, tabi ti ẹjẹ́ rẹ ti iwọ jẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwa rẹ, tabi ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ rẹ:

Deu 12