Deu 11:22-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Nitoripe bi ẹnyin ba pa gbogbo ofin yi mọ́ gidigidi, ti mo palaṣẹ fun nyin, lati ma ṣe e; lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati faramọ́ ọ;

23. Nigbana ni OLUWA yio lé gbogbo awọn orilẹ-ède wọnyi jade kuro niwaju nyin, ẹnyin o si gbà orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù nyin lọ.

24. Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀ yio jẹ́ ti nyin: lati aginjù nì, ati Lebanoni, lati odò nla nì, odò Euferate, ani dé ikẹhin okun ni yio jẹ́ opinlẹ nyin.

25. Kò sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju nyin: OLUWA Ọlọrun nyin, yio fi ìbẹru nyin ati ìfoiya nyin sara gbogbo ilẹ ti ẹnyin o tẹ̀, bi on ti wi fun nyin.

26. Wò o, emi fi ibukún ati egún siwaju nyin li oni;

27. Ibukún, bi ẹnyin ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni:

28. Ati egún, bi ẹnyin kò ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́ ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.

29. Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, ki iwọ ki o ma sure lori òke Gerisimu, ki iwọ ki o si ma gegun lori òke Ebali.

30. Awọn kọ ha wà ni ìha keji Jordani, li ọ̀na ìwọ-õrùn, ni ilẹ awọn ara Kenaani, ti ngbé Araba ti o kọjusi Gilgali, lẹba igbó More?

31. Nitoripe ẹnyin o gòke Jordani lati wọle ati lati gbà ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin, ẹnyin o si gbà a, ẹnyin o si ma gbé inu rẹ̀.

Deu 11