1. NITORINA ki iwọ ki o fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma pa ikilọ̀ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ofin rẹ̀ mọ́, nigbagbogbo.
2. Ki ẹnyin ki o si mọ̀ li oni: nitoripe awọn ọmọ nyin ti emi nsọ fun ti kò mọ̀, ti kò si ri ibawi OLUWA Ọlọrun nyin, titobi rẹ̀, ọwọ́ agbara rẹ̀, ati ninà apa rẹ̀,
3. Ati iṣẹ-àmi rẹ̀, ati iṣẹ rẹ̀, ti o ṣe lãrin Egipti, si Farao ọba Egipti, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀;
4. Ati ohun ti o ṣe si ogun Egipti, si ẹṣin wọn, ati kẹkẹ́-ogun wọn; bi o ti mu ki omi Okun Pupa bò wọn mọlẹ bi nwọn ti nlepa nyin lọ, ati bi OLUWA ti run wọn titi di oni-oloni;
5. Ati bi o ti ṣe si nyin li aginjù, titi ẹnyin fi dé ihin yi;
6. Ati bi o ti ṣe si Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu, ọmọ Reubeni; bi ilẹ ti yà ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì, ati ara ile wọn, ati agọ́ wọn, ati ohun alãye gbogbo ti o tẹle wọn, lãrin gbogbo Israeli:
7. Ṣugbọn oju nyin ti ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA ti o ṣe.
8. Nitorina ki ẹnyin ki o pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, ki ẹnyin ki o le lagbara, ki ẹnyin ki o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki ẹ si gbà ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a;
9. Ati ki ẹnyin ki o le mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
10. Nitoripe ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a, kò dabi ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin ti jade wá, nibiti iwọ gbìn irugbìn rẹ, ti iwọ si nfi ẹsẹ̀ rẹ bomirin i, bi ọgbà ewebẹ̀:
11. Ṣugbọn ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a, ilẹ òke ati afonifoji ni, ti o si nmu omi òjo ọrun: