Deu 10:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Kìki OLUWA ni inudidùn si awọn baba rẹ lati fẹ́ wọn, on si yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, ani ẹnyin jù gbogbo enia lọ, bi o ti ri li oni yi.

16. Nitorina ẹ kọ àiya nyin nilà, ki ẹ má si ṣe ọlọrùn lile mọ́.

17. Nitori OLUWA Ọlọrun nyin, Ọlọrun awọn ọlọrun ni ati OLUWA awọn oluwa, Ọlọrun titobi, alagbara, ati ẹ̀lẹru, ti ki iṣe ojuṣaju, bẹ̃ni ki igba abẹtẹlẹ.

18. On ni ima ṣe idajọ alainibaba ati opó, o si fẹ́ alejò, lati fun u li onjẹ ati aṣọ.

19. Nitorina ki ẹnyin ki o ma fẹ́ alejò: nitoripe ẹnyin ṣe alejò ni ilẹ Egipti.

20. Ki iwọ ki o ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ; on ni ki iwọ ki o ma sìn, on ni ki iwọ ki o si faramọ́, orukọ rẹ̀ ni ki o si ma fi bura.

21. On ni iyìn rẹ, on si li Ọlọrun rẹ, ti o ṣe ohun nla ati ohun ẹ̀lẹru wọnni fun ọ, ti oju rẹ ri.

22. Awọn baba rẹ sọkalẹ lọ si Egipti ti awọn ti ãdọrin enia; ṣugbọn nisisiyi OLUWA Ọlọrun rẹ sọ ọ dabi irawọ ọrun li ọ̀pọlọpọ.

Deu 10