Deu 10:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA li OLUWA wi fun mi pe, Gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju, ki o si tọ̀ mi wá lori òke na, ki o si ṣe apoti igi kan.

2. Emi o si kọ ọ̀rọ ti o ti wà lara walã iṣaju ti iwọ fọ́, sara walã wọnyi, iwọ o si fi wọn sinu apoti na.

3. Emi si ṣe apoti igi ṣittimu kan, mo si gbẹ́ walã okuta meji bi ti isaju, mo si lọ sori òke na, walã mejeji si wà li ọwọ́ mi.

4. On si kọ ofin mẹwẹwa sara walã wọnni, gẹgẹ bi o ti kọ ti iṣaju, ti OLUWA sọ fun nyin lori òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì; OLUWA si fi wọn fun mi.

5. Mo si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke na wá, mo si fi walã wọnni sinu apoti ti mo ti ṣe; nwọn si wà nibẹ̀, bi OLUWA ti paṣẹ fun mi.

6. (Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati Beerotu ti iṣe ti awọn ọmọ Jaakani lọ si Mosera: nibẹ̀ li Aaroni gbé kú, nibẹ̀ li a si sin i; Eleasari ọmọ rẹ̀ si nṣe iṣẹ alufa ni ipò rẹ̀.

7. Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Gudgoda; ati lati Gudgoda lọ si Jotbati, ilẹ olodò omi.

8. Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi.

9. Nitorina ni Lefi kò ṣe ní ipín tabi iní pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; OLUWA ni iní rẹ̀, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun ti ṣe ileri fun u.)

10. Emi si duro lori òke na, gẹgẹ bi ìgba iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru: OLUWA si gbọ́ ti emi ni igbana pẹlu, OLUWA kò si fẹ́ run ọ.

11. OLUWA si wi fun mi pe, Dide, mú ọ̀na ìrin rẹ niwaju awọn enia, ki nwọn ki o le wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki nwọn ki o le gbà ilẹ na, ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.

12. Njẹ nisisiyi, Israeli, kini OLUWA Ọlọrun rẹ mbère lọdọ rẹ, bikoṣe lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, lati ma fẹ́ ẹ, ati lati ma sìn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo,

Deu 10