Deu 1:3-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. O si ṣe nigbati o di ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fun u li aṣẹ fun wọn;

4. Lẹhin igbati o pa Sihoni tán ọba awọn ọmọ Amori, ti o ngbé Heṣboni, ati Ogu ọba Baṣani, ti o ngbé Aṣtarotu, ni Edrei:

5. Ni ìha ihin Jordani, ni ilẹ Moabu, on ni Mose bẹ̀rẹsi isọ asọye ofin yi, wipe,

6. OLUWA Ọlọrun wa sọ fun wa ni Horebu, wipe, Ẹ gbé ori òke yi pẹ to:

7. Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate.

8. Wò o, mo ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọ̀ ọ lọ ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn lẹhin wọn.

9. Mo si sọ fun nyin ni ìgba na pe, Emi nikan kò le rù ẹrù nyin:

10. OLUWA Ọlọrun nyin ti mu nyin bisi i, si kiyesi i, li oni ẹnyin dabi irawọ oju-ọrun fun ọ̀pọ.

11. Ki OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin ki o fi kún iye nyin ni ìgba ẹgbẹrun, ki o si busi i fun nyin, bi o ti ṣe ileri fun nyin!

12. Emi o ti ṣe le nikan rù inira nyin, ati ẹrù nyin, ati ìja nyin?

13. Ẹ mú awọn ọkunrin ọlọgbọ́n wá, ati amoye, ati ẹniti a mọ̀ ninu awọn ẹ̀ya nyin, emi o si fi wọn jẹ olori nyin.

Deu 1