Gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, gbogbo ibi wọnyi wá sori wa: bẹ̃li awa kò si wá ojurere niwaju Oluwa, Ọlọrun wa, ki awa ki o le yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, ki a si moye otitọ rẹ.