Dan 7:7-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa.

8. Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà.

9. Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná.

10. Iṣàn iná nṣẹyọ, o si ntu jade lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹ̃gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbarun duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣi iwe wọnni silẹ.

11. Nigbana ni mo wò nitori ohùn ọ̀rọ nla ti iwo na nsọ: mo si wò titi a fi pa ẹranko na, a si pa ara rẹ̀ run, a si sọ ọ sinu ọwọ iná ti njo.

12. Bi o ṣe ti awọn ẹranko iyokù ni, a ti gba agbara wọn kuro: nitori a ti yàn akokò ati ìgba fun wọn bi olukulùku yio ti pẹ tó.

13. Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀.

14. A si fi agbara ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sìn i; agbara ijọba rẹ̀ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a kì yio rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyiti a kì yio le parun.

15. Ẹmi emi Danieli si rẹwẹsi ninu ara mi, iran ori mi si mu mi dãmu.

16. Mo sunmọ ọkan ninu awọn ti o duro lapakan, mo si bi i lere otitọ gbogbo nkan wọnyi. Bẹ̃li o sọ fun mi, o si fi itumọ nkan wọnyi hàn fun mi.

17. Awọn ẹranko nla wọnyi, ti o jẹ mẹrin, li awọn ọba mẹrin ti yio dide li aiye.

18. Ṣugbọn awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo julọ yio gbà ijọba, nwọn o si jogun ijọba na lai, ani titi lailai.

19. Nigbana ni mo si nfẹ imọ̀ otitọ ti ẹranko kẹrin, eyiti o yatọ si gbogbo awọn iyokù, ti o lẹrù gidigidi, eyi ti ehin rẹ̀ jẹ irin, ti ẽkanna rẹ̀ jẹ idẹ, ti njẹ, ti nfọ tũtu, ti o si nfi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ.

20. Ati niti iwo mẹwa ti o wà li ori rẹ̀, ati omiran na ti o yọ soke, niwaju eyiti mẹta si ṣubu; ani iwo na ti o ni oju, ati ẹnu ti nsọ̀rọ ohun nlanla, eyi ti oju rẹ̀ si koro jù ti awọn ẹgbẹ rẹ̀ lọ.

21. Mo ri iwo kanna si mba awọn enia-mimọ́ jagun, o si bori wọn.

22. Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na.

23. Bẹ̃li o wipe, Ẹranko kẹrin nì yio ṣe ijọba kẹrin li aiye, eyiti yio yàtọ si gbogbo ijọba miran, yio pa gbogbo aiye rẹ́, yio si tẹ̀ ẹ molẹ, yio si fọ ọ tũtu.

Dan 7