24. Nitorina ni a ṣe rán ọwọ na lati ọdọ rẹ̀ wá; ti a si fi kọ iwe yi.
25. Eyiyi si ni iwe na ti a kọ, MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.
26. Eyi ni itumọ ohun na: MENE, Ọlọrun ti ṣirò ijọba rẹ, o si pari rẹ̀.
27. TEKELI; A ti wọ̀n ọ wò ninu ọ̀ṣuwọn, iwọ kò si to.
28. PERESINI; A pin ijọba rẹ, a si fi fun awọn ara Media, ati awọn ara Persia.