Dan 5:17-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nigbana ni Danieli dahùn, o si wi niwaju ọba pe, Jẹ ki ẹ̀bun rẹ gbe ọwọ rẹ, ki o si fi ẹsan rẹ fun ẹlomiran; ṣugbọn emi o ka iwe na fun ọba, emi o si fi itumọ rẹ̀ hàn fun u.

18. Iwọ ọba! Ọlọrun Ọga-ogo fi ijọba, ati ọlanla, ati ogo, ati ọlá fun Nebukadnessari, baba rẹ:

19. Ati nitori ọlanla ti o fi fun u, gbogbo enia, orilẹ, ati ède gbogbo nwariri, nwọn si mbẹ̀ru niwaju rẹ̀: ẹniti o wù u, a pa, ẹniti o si wù u, a da si lãye; ẹniti o wù u, a gbé ga; ẹniti o si wú u, a rẹ̀ silẹ.

20. Ṣugbọn nigbati ọkàn rẹ̀ gbega, ti inu rẹ̀ si le nipa igberaga, a mu u kuro lori itẹ rẹ̀, nwọn si gba ogo rẹ̀ lọwọ rẹ̀:

21. A si le e kuro lãrin awọn ọmọ enia; a si ṣe aiya rẹ̀ dabi ti ẹranko, ibugbe rẹ̀ si wà lọdọ awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ; nwọn si fi koriko bọ́ ọ gẹgẹ bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara; titi on fi mọ̀ pe Ọlọrun Ọga-ogo ni iṣe alakoso ninu ijọba enia, on a si yàn ẹnikẹni ti o wù u ṣe olori rẹ̀.

Dan 5