10. Bayi ni iran ori mi lori akete mi; mo ri, si kiyesi i, igi kan duro li arin aiye, giga rẹ̀ si pọ̀ gidigidi.
11. Igi na si dagba, o si lagbara, giga rẹ̀ si kan ọrun, a si ri i titi de gbogbo opin aiye.
12. Ewe rẹ̀ lẹwa, eso rẹ̀ si pọ̀, lara rẹ̀ li onjẹ wà fun gbogbo aiye: abẹ rẹ̀ jẹ iboji fun awọn ẹranko igbẹ, ati lori ẹka rẹ̀ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun ngbe, ati lati ọdọ rẹ̀ li a si ti mbọ gbogbo ẹran-ara.
13. Mo ri ninu iran ori mi lori akete mi, si kiye si i, oluṣọ, ani ẹni mimọ́ kan sọkalẹ lati ọrun wá;
14. O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀:
15. Ṣugbọn, fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ ninu ilẹ, ani pẹlu ide ninu irin ati idẹ ninu koriko tutu igbẹ; si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki o si ni ipin rẹ̀ ninu koriko ilẹ aiye pẹlu awọn ẹranko:
16. Ki a si pa aiya rẹ̀ da kuro ni ti enia, ki a si fi aiya ẹranko fun u, ki igba meje ki o si kọja lori rẹ̀.
17. Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.