Nigbana ni awọn ọmọ-alade, bãlẹ, balogun, ati awọn ìgbimọ ọba ti o pejọ ri pe iná kò lagbara lara awọn ọkunrin wọnyi, bẹ̃ni irun ori wọn kan kò jona, bẹ̃li aṣọ wọn kò si pada, õrùn iná kò tilẹ kọja lara wọn.