Dan 2:27-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Danieli si dahùn niwaju ọba, o si wipe, Aṣiri ti ọba mbère, awọn ọlọgbọ́n, awọn oṣó, awọn amoye, ati awọn alafọṣẹ, kò le fi hàn fun ọba.

28. Ṣugbọn Ọlọrun kan mbẹ li ọrun ti o nfi aṣiri hàn, ẹniti o si fi hàn fun Nebukadnessari ohun ti mbọ wá ṣe ni ikẹhin ọjọ. Alá rẹ, ati iran ori rẹ lori akete rẹ, ni wọnyi;

29. Ọba, iwọ nronu lori akete rẹ, ohun ti yio ṣe lẹhin ọla, ati ẹniti o nfi aṣiri hàn funni mu ọ mọ̀ ohun ti mbọ wá ṣe.

30. Ṣugbọn bi o ṣe temi ni, a kò fi aṣiri yi hàn fun mi nitori ọgbọ́n ti emi ni jù ẹni alãye kan lọ, ṣugbọn nitori ki a le fi itumọ na hàn fun ọba, ati ki iwọ ki o le mọ̀ èro ọkàn rẹ.

31. Iwọ ọba nwò, si kiyesi, ere nla kan. Ere giga yi, ti didan rẹ̀ pọ̀ gidigidi, o duro niwaju rẹ, ìrí rẹ̀ si ba ni lẹ̀ru gidigidi.

32. Eyi ni ere na; ori rẹ̀ jẹ wura daradara, aiya ati apa rẹ̀ jẹ fadaka, inu ati ẹ̀gbẹ rẹ̀ jẹ idẹ,

33. Itan rẹ̀ jẹ irin, ẹsẹ rẹ̀ si jẹ apakan irin, apakan amọ̀.

34. Iwọ ri titi okuta kan fi wá laisi ọwọ, o si kọlu ere na lẹsẹ rẹ̀, ti iṣe ti irin ati amọ̀, o si fọ́ wọn tũtu.

35. Nigbana li a si fọ irin, amọ̀, idẹ, fadaka ati wura pọ̀ tũtu, o si dabi iyangbo ipaka nigba ẹ̀run; afẹfẹ si gbá wọn lọ, ti a kò si ri ibi kan fun wọn mọ́: okuta ti o si fọ ere na si di òke nla, o si kún gbogbo aiye.

36. Eyiyi li alá na; awa o si sọ itumọ rẹ̀ pẹlu niwaju ọba.

Dan 2