1. ATI li ọdun keji ijọba Nebukadnessari, Nebukadnessari lá alá nipa eyi ti ọkàn rẹ̀ kò fi le ilẹ ninu rẹ̀, ti orun si dá loju rẹ̀.
2. Nigbana ni ọba paṣẹ pe, ki a pè awọn amoye ati ọlọgbọ́n, ati awọn oṣó, ati awọn Kaldea wá, lati fi alá ọba na hàn fun u. Bẹ̃ni nwọn si duro niwaju ọba.
3. Ọba si wi fun wọn pe, mo lá alá kan, ọkàn mi kò si le ilẹ lati mọ̀ alá na.
4. Nigbana ni awọn Kaldea wi fun ọba li ede awọn ara Siria pe, Ki ọba ki o pẹ́: rọ́ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ, awa o si fi itumọ̀ na hàn.
5. Ọba dahùn o si wi fun awọn Kaldea pe, ohun na ti kuro li ori mi: bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, a o ké nyin wẹwẹ, a o si sọ ile nyin di ãtàn.
6. Ṣugbọn bi ẹnyin ba fi alá na hàn, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, ẹnyin o gba ẹ̀bun ati ọrẹ ati ọlá nla li ọwọ mi: nitorina, ẹ fi alá na hàn fun mi, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu.