Dan 11:16-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ṣugbọn ẹniti o tọ̀ ọ wá yio mã ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu ara rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio duro niwaju rẹ̀; on o si duro ni ilẹ daradara nì, ti yio si fi ọwọ rẹ̀ parun.

17. On o si gbé oju rẹ̀ soke lati wọ̀ ọ nipa agbara gbogbo ijọba rẹ̀, yio si ba a dá majẹmu, bẹ̃ni yio ṣe; on o si fi ọmọbinrin awọn obinrin fun u, lati bà a jẹ: ṣugbọn on kì yio duro, bẹ̃ni kì yio si ṣe tirẹ̀.

18. Lẹhin eyi, yio kọ oju rẹ̀ si erekuṣu wọnni, yio si gbà ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn balogun kan fun ara rẹ̀, yio fi opin si ẹ̀gan rẹ̀: ati nipò eyi, yio mu ẹ̀gan rẹ̀ pada wá sori ara rẹ̀.

19. Nigbana ni yio si yi oju rẹ̀ pada si ilu olodi ontikararẹ̀: ṣugbọn yio kọsẹ, yio si ṣubu, a kì yio si ri i mọ.

20. Nigbana ni ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀ ti yio mu agbowode kan rekọja ninu ogo ijọba (ilẹ Juda): ṣugbọn niwọn ijọ melokan li a o si pa a run, kì yio ṣe nipa ibinu tabi loju ogun.

21. Ni ipò rẹ̀ li enia lasan kan yio dide, ẹniti nwọn kì yio fi ọlá ọba fun: ṣugbọn yio wá lojiji, yio si fi arekereke gbà ijọba.

22. Ogun ti mbò ni mọlẹ li a o fi bò wọn mọlẹ niwaju rẹ̀, a o si fọ ọ tũtu, ati pẹlu ọmọ-alade majẹmu kan.

23. Ati lẹhin igbati a ba ti ba a ṣe ipinnu tan, yio fi ẹ̀tan ṣiṣẹ: yio si gòke lọ, yio si fi enia diẹ bori.

24. Yio si wọ̀ gbogbo ibi igberiko ọlọra; yio si ṣe ohun ti awọn baba rẹ̀ kò ṣe ri, tabi awọn baba nla rẹ̀; yio si fọn ikogun, ìfa, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ ká si ãrin wọn: yio si gbèro tẹlẹ si ilu olodi, ani titi akokò kan.

25. Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i.

Dan 11