Orin inu tempeli yio si jẹ hihu li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi: okú pupọ̀ ni yio wà ni ibi gbogbo; nwọn o ma fi idakẹ jù wọn sode.