Amo 8:10-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Emi o si yi àse nyin padà si ọ̀fọ, ati orin nyin gbogbo si ohùn-rére ẹkún: emi o si mu aṣọ ọ̀fọ wá si ẹgbẹ̀ gbogbo, ati pipá ori, si gbogbo ori; emi o si ṣe e ki o dàbi iṣọ̀fọ fun ọmọ kanṣoṣo ti a bi; ati opin rẹ̀ bi ọjọ kikorò.

11. Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa Ọlọrun wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, kì iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ́ ọ̀rọ Oluwa:

12. Nwọn o si ma rìn kiri lati okun de okun, ati lati ariwa ani titi de ila-õrun, nwọn o sare siwá sẹhìn lati wá ọ̀rọ Oluwa, nwọn kì yio si ri i.

13. Li ọjọ na li awọn arẹwà wundia, ati awọn ọdọmọkunrin yio daku fun ongbẹ.

Amo 8