4. Bayi li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si wò o, Oluwa Ọlọrun pè lati fi iná jà, o si jó ibú nla nì run, o si jẹ apakan run.
5. Nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, dawọ duro, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on.
6. Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Eyi pẹlu kì yio ṣe, li Oluwa Ọlọrun wi.
7. Bayi li on fi hàn mi: si wò o, Oluwa duro lori odi kan, ti a fi okùn-ìwọn ti o run mọ, ti on ti okùn-ìwọn ti o run li ọwọ́ rẹ̀.
8. Oluwa si wi fun mi pe, Amosi, kini iwọ ri? Emi si wipe, Okùn-ìwọn kan ti o run ni. Nigbana ni Oluwa wipe, Wò o, emi o fi okùn-ìwọn rirun kan le ilẹ lãrin Israeli enia mi: emi kì yio si tun kọja lọdọ wọn mọ: