12. Amasiah sọ fun Amosi pẹlu pe, Iwọ ariran, lọ, salọ si ilẹ Juda, si ma jẹun nibẹ̀, si ma sọtẹlẹ nibẹ̀:
13. Ṣugbọn máṣe sọtẹlẹ̀ mọ ni Beteli: nitori ibi mimọ́ ọba ni, ãfin ọba si ni.
14. Nigbana ni Amosi dahùn, o si wi fun Amasiah pe, Emi ki iṣe woli ri, bẹ̃ni emi kì iṣe ọmọ woli, ṣugbọn olùṣọ-agùtan li emi ti iṣe ri, ati ẹniti iti ma ká eso ọpọ̀tọ:
15. Oluwa si mu mi, bi mo ti ntọ̀ agbo-ẹran lẹhìn, Oluwa si wi fun mi pe, Lọ, sọtẹlẹ̀ fun Israeli enia mi.
16. Njẹ nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Iwọ wipe, Máṣe sọtẹlẹ̀ si Israeli, má si jẹ ki ọ̀rọ rẹ kán silẹ si ile Isaaki.
17. Nitorina bayi li Oluwa wi; Obinrin rẹ yio di panṣagà ni ilu, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, yio ti ipa idà ṣubu; ilẹ rẹ li a o si fi okùn pin; iwọ o si kú ni ilẹ aimọ́: nitõtọ, a o si kó Israeli lọ ni igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀.