Nitori mo mọ̀ onirũru irekọja nyin, ati ẹ̀ṣẹ nla nyin: nwọn npọ́n olododo loju, nwọn ngbà owo abẹ̀tẹlẹ, nwọn si nyi awọn talakà si apakan ni bodè, kuro ninu are wọn.