Amo 4:10-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Mo ti rán ajàkalẹ-arùn si ãrin nyin, gẹgẹ bi ti Egipti: awọn ọdọmọkunrin nyin li emi si ti fi idà pa, nwọn si ti kó ẹṣin nyin ni igbèkun pẹlu; mo si ti jẹ ki õrùn ibùdo nyin bù soke wá si imú nyin: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

11. Mo ti bì ṣubu ninu nyin, bi Ọlọrun ti bì Sodomu on Gomorra ṣubu, ẹnyin si dàbi oguná ti a fà yọ kuro ninu ijoná: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

12. Nitorina, bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israeli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ, iwọ Israeli.

13. Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

Amo 4