Amo 3:4-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ọmọ kiniun yio ha ké jade ninu ihò rẹ̀, bi kò ri nkan mu?

5. Ẹiyẹ le lu okùn ni ilẹ, nibiti okùn didẹ kò gbe si fun u? okùn ha le ré kuro lori ilẹ, laijẹ pe o mu nkan rara?

6. A le fun ipè ni ilu, ki awọn enia má bẹ̀ru? tulasi ha le wà ni ilu, ki o má ṣepe Oluwa li o ṣe e?

7. Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀.

8. Kiniun ti ké ramùramù, tani kì yio bẹ̀ru? Oluwa Ọlọrun ti sọ̀rọ, tani lè ṣe aisọtẹlẹ?

9. Ẹ kede li ãfin Aṣdodu, ati li ãfin ni ilẹ Egipti, ki ẹ si wipe, Pè ara nyin jọ lori awọn oke nla Samaria, ki ẹ si wò irọkẹ̀kẹ nla lãrin rẹ̀, ati inilara lãrin rẹ̀.

10. Nitori nwọn kò mọ̀ bi ati ṣe otitọ, li Oluwa wi, nwọn ti kó ìwa-ipá ati ìwa-olè jọ li ãfin wọn.

11. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ọta kan yio si wà yi ilẹ na ka; on o si sọ agbara rẹ kalẹ kuro lara rẹ, a o si kó ãfin rẹ wọnni.

Amo 3