9. Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá.
10. Emi mu nyin goke pẹlu lati ilẹ Egipti wá, mo si sìn nyin li ogoji ọdun là aginjù ja, lati ni ilẹ awọn Amori.
11. Mo si gbe ninu ọmọkunrin nyin dide lati jẹ woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin lati jẹ Nasarite. Bẹ̃ ki o ri, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi.
12. Ṣugbọn ẹnyin fun awọn Nasarite ni ọti-waini mu, ẹ si paṣẹ fun awọn woli pe, Ẹ máṣe sọtẹlẹ.