6. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn tà olododo fun fàdakà, ati talakà fun bàta ẹsẹ̀ mejeji;
7. Nwọn tẹ ori talaka sinu eruku ilẹ, nwọn si yi ọ̀na ọlọkàn tutù po: ati ọmọ ati baba rẹ̀ nwọle tọ̀ wundia kan, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ.
8. Nwọn si dùbulẹ le aṣọ ti a fi lelẹ fun ògo lẹba olukuluku pẹpẹ, nwọn si mu ọti-waini awọn ti a yá, ni ile ọlọrun wọn.
9. Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá.
10. Emi mu nyin goke pẹlu lati ilẹ Egipti wá, mo si sìn nyin li ogoji ọdun là aginjù ja, lati ni ilẹ awọn Amori.