A. Oni 9:53-57 Yorùbá Bibeli (YCE)

53. Obinrin kan si sọ ọlọ lù Abimeleki li ori, o si fọ́ ọ li agbári.

54. Nigbana li o pè ọmọkunrin ti nrù ihamọra rẹ̀ kánkan, o si wi fun u pe, Fà idà rẹ yọ, ki o si pa mi, ki awọn enia ki o má ba wi nipa ti emi pe, Obinrin li o pa a. Ọmọkunrin rẹ̀ si gún u, bẹ̃li o si kú.

55. Nigbati awọn ọkunrin Israeli si ri pe, Abimeleki kú, nwọn si lọ olukuluku si ipò rẹ̀.

56. Bayi li Ọlọrun san ìwa buburu Abimeleki, ti o ti hù si baba rẹ̀, niti pe, o pa ãdọrin awọn arakunrin rẹ̀:

57. Ati gbogbo ìwa buburu awọn ọkunrin Ṣekemu li Ọlọrun si múpada sori wọn: egún Jotamu ọmọ Jerubbaali si ṣẹ sori wọn.

A. Oni 9