39. Gaali si jade niwaju awọn ọkunrin Ṣekemu, o si bá Abimeleki jà.
40. Abimeleki si lé e, on si sá niwaju rẹ̀, ọ̀pọlọpọ ninu nwọn ti o gbọgbẹ si ṣubu, titi dé ẹnu-ọ̀na ibode.
41. Abimeleki si joko ni Aruma: Sebulu si tì Gaali ati awọn arakunrin rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe joko ni Ṣekemu.
42. O si ṣe ni ijọ keji, ti awọn enia si jade lọ sinu oko; nwọn si sọ fun Abimeleki.
43. On si mu awọn enia, o si pín wọn si ipa mẹta, o si ba ninu oko: o si wò, si kiyesi i, awọn enia nti ilu jade wá; on si dide si wọn, o si kọlù wọn.
44. Abimeleki, ati ẹgbẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀ sure siwaju, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: ẹgbẹ meji si sure si gbogbo awọn enia na ti o wà ninu oko, nwọn si kọlù wọn.
45. Abimeleki si bá ilu na jà ni gbogbo ọjọ́ na; on si kó ilu na, o si pa awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, o si wó ilu na palẹ, o si fọn iyọ̀ si i.
46. Nigbati gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu gbọ́, nwọn si wọ̀ inu ile-ẹṣọ́ oriṣa Eliberiti lọ.
47. A si sọ fun Abimeleki pe, gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu kó ara wọn jọ pọ̀.
48. Abimeleki si gùn ori òke Salmoni lọ, on ati gbogbo enia ti o wà pẹlu rẹ̀; Abimeleki si mu ãke kan li ọwọ́ rẹ̀, o si ke ẹka kan kuro lara igi, o si mú u, o si gbé e lé èjika rẹ̀, o si wi fun awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ pe, Ohun ti ẹnyin ri ti emi ṣe, ẹ yára, ki ẹ si ṣe bi emi ti ṣe.
49. Gbogbo awọn enia na pẹlu, olukuluku si ke ẹka tirẹ̀, nwọn si ntọ̀ Abimeleki lẹhin, nwọn si fi wọn sinu ile-ẹṣọ́ na, nwọn si tinabọ ile na mọ́ wọn lori, tobẹ̃ ti gbogbo awọn ọkunrin ile-ẹṣọ́ Ṣekemu fi kú pẹlu, ìwọn ẹgbẹrun enia, ọkunrin ati obinrin.
50. Nigbana ni Abimeleki lọ si Tebesi, o si dótì Tebesi, o si kó o.
51. Ṣugbọn ile-ẹṣọ́ ti o lagbara wà ninu ilu na, nibẹ̀ ni gbogbo awọn ọkunrin ati awọn obinrin, ati gbogbo awọn ẹniti o wà ni ilu na gbé sá si, nwọn si fara wọn mọ́ ibẹ̀; nwọn si gòke ile-ẹṣọ́ na lọ.
52. Abimeleki si wá si ibi ile-ẹṣọ́ na, o si bá a jà, o si sunmọ ẹnu-ọ̀na ile-ẹṣọ na lati fi iná si i.
53. Obinrin kan si sọ ọlọ lù Abimeleki li ori, o si fọ́ ọ li agbári.
54. Nigbana li o pè ọmọkunrin ti nrù ihamọra rẹ̀ kánkan, o si wi fun u pe, Fà idà rẹ yọ, ki o si pa mi, ki awọn enia ki o má ba wi nipa ti emi pe, Obinrin li o pa a. Ọmọkunrin rẹ̀ si gún u, bẹ̃li o si kú.
55. Nigbati awọn ọkunrin Israeli si ri pe, Abimeleki kú, nwọn si lọ olukuluku si ipò rẹ̀.