A. Oni 9:2-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Emi bẹ̀ nyin, ẹ sọ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu pe, Ẽwo li o rọ̀run fun nyin, ki gbogbo awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, ki o ṣe olori nyin, tabi ki ẹnikan ki o ṣe olori nyin? ki ẹnyin ki o ranti pẹlu pe, emi li egungun nyin, ati ẹran ara nyin.

3. Awọn arakunrin iya rẹ̀ si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi nitori rẹ̀ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu: àiya wọn si tẹ̀ si ti Abimeleki; nitori nwọn wipe, Arakunrin wa ni iṣe.

4. Nwọn si fun u li ãdọrin owo fadakà lati inu ile Baali-beriti wá, Abimeleki si fi i bẹ̀ awọn enia lasan ati alainilari li ọ̀wẹ, nwọn si ntẹ̀le e.

5. On si lọ si ile baba rẹ̀ ni Ofra, o si pa awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, lori okuta kan: ṣugbọn o kù Jotamu abikẹhin ọmọ Jerubbaali; nitoriti o sapamọ́.

6. Gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu si kó ara wọn jọ, ati gbogbo awọn ara ile Millo, nwọn lọ nwọn si fi Abimeleki jẹ́ ọba, ni ibi igi-oaku ile-ẹṣọ́ ti mbẹ ni Ṣekemu.

7. Nigbati nwọn si sọ fun Jotamu, on si lọ o si duro lori òke Gerisimu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o kigbe, o si wi fun wọn pe, Ẹ fetisi ti emi, ẹnyin ọkunrin Ṣekemu, ki Ọlọrun ki o le fetisi ti nyin.

8. Awọn igi lọ li akokò kan ki nwọn ki o le fi ọba jẹ́ lori wọn; nwọn si wi fun igi olifi pe, Wá jọba lori wa.

9. Ṣugbọn igi olifi wi fun wọn pe, Emi ha le fi ọrá mi silẹ, nipa eyiti nwọn nfi mi bù ọlá fun Ọlọrun ati enia, ki emi ki o si wá ṣe olori igi?

10. Awọn igi si wi fun igi ọpọtọ́ pe, Iwọ wá jọba lori wa.

11. Ṣugbọn igi ọpọtọ́ wi fun wọn pe, Emi le fi adùn mi silẹ, ati eso mi daradara, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi?

12. Awọn igi si wi fun àjara pe, Iwọ wá jọba lori wa.

13. Àjara si wi fun wọn pe, Ki emi ki o fi ọti-waini mi silẹ, eyiti nmu inu Ọlọrun ati enia dùn, ki emi ki o si wá ṣe olori awọn igi?

14. Nigbana ni gbogbo igi si wi fun igi-ẹgún pe, Iwọ wá jọba lori wa.

15. Igi-ẹgún si wi fun awọn igi pe, Bi o ba ṣepe nitõtọ li ẹnyin fi emi jẹ́ ọba lori nyin, njẹ ẹ wá sá si abẹ ojiji mi: bi kò ba si ṣe bẹ̃, jẹ ki iná ki o ti inu igi-ẹgún jade wá, ki o si jó awọn igi-kedari ti Lebanoni run.

16. Njẹ nitorina, bi ẹnyin ba ṣe otitọ, ati eyiti o pé, ni ti ẹnyin fi Abimeleki jẹ ọba, ati bi ẹnyin ba si ṣe rere si Jerubbaali ati si ile rẹ̀, ti ẹnyin si ṣe si i gẹgẹ bi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;

17. (Nitoriti baba mi jà fun nyin, o si fi ẹmi rẹ̀ wewu, o si gbà nyin kuro li ọwọ Midiani:

A. Oni 9