A. Oni 7:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, dide ni kùtukutu, nwọn si dó lẹba orisun Harodu: ibudó Midiani si wà ni ìha ariwa wọn, nibi òke More, li afonifoji.

2. OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia ti o wà lọdọ rẹ pọ̀ju fun mi lati fi awọn Midiani lé wọn lọwọ, ki Israeli ki o má ba gbé ara wọn ga si mi, pe, Ọwọ́ mi li o gbà mi là.

3. Njẹ nitorina, lọ kede li etí awọn enia na, wipe, Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹ̀ru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ. Ẹgbã mọkanla si pada ninu awọn enia na; awọn ti o kù si jẹ́ ẹgba marun.

A. Oni 7