A. Oni 6:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje.

2. Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni.

3. O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá;

4. Nwọn a si dótì wọn, nwọn a si run eso ilẹ na, titi iwọ o fi dé Gasa, nwọn ki isi fi onjẹ silẹ ni Israeli, tabi agutan, tabi akọ-malu, tabi kẹtẹkẹtẹ.

5. Nitoriti nwọn gòke wá ti awọn ti ohunọ̀sin wọn ati agọ́ wọn, nwọn si wá bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; awọn ati awọn ibakasiẹ wọn jẹ́ ainiye: nwọn si wọ̀ inu ilẹ na lati jẹ ẹ run.

6. Oju si pọ́n Israeli gidigidi nitori awọn Midiani; awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA.

A. Oni 6