1. AWỌN ọmọ Israeli si ṣe buburu loju OLUWA: OLUWA si fi wọn lé Midiani lọwọ li ọdún meje.
2. Ọwọ́ Midiani si le si Israeli: ati nitori Midiani awọn ọmọ Israeli wà ihò wọnni fun ara wọn, ti o wà ninu òke, ati ninu ọgbun, ati ni ibi-agbara wọnni.
3. O si ṣe, bi Israeli ba gbìn irugbìn, awọn Midiani a si gòke wá, ati awọn Amaleki, ati awọn ọmọ ìha ìla-õrùn; nwọn a si gòke tọ̀ wọn wá;