A. Oni 5:18-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Sebuluni li awọn enia, ti o fi ẹmi wọn wewu ikú, ati Naftali, ni ibi giga pápa.

19. Awọn ọba wá nwọn jà; nigbana li awọn ọba Kenaani jà ni Taanaki leti odò Megiddo: nwọn kò si gbà ère owo.

20. Nwọn jà lati ọrun wá, awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà.

21. Odò Kiṣoni gbá wọn lọ, odò igbani, odò Kiṣoni. Hã ọkàn mi, ma yan lọ ninu agbara.

22. Nigbana ni patako ẹsẹ̀ ẹṣin kì ilẹ, nitori ire-sisá, iré-sisá awọn alagbara wọn.

23. Ẹ fi Merosi bú, bẹ̃li angeli OLUWA wi, ẹ fi awọn ara inu rẹ̀ bú ibú kikorò; nitoriti nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara.

24. Ibukún ni fun Jaeli aya Heberi ọmọ Keni jù awọn obinrin lọ, ibukún ni fun u jù awọn obinrin lọ ninu agọ́.

25. O bère omi, o fun u ni warà; o mu ori-amọ tọ̀ ọ wá ninu awo iyebiye.

26. O nà ọwọ́ rẹ̀ mú iṣo, ati ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú òlu awọn ọlọnà; òlu na li o si fi lù Sisera, o gba mọ́ ọ li ori, o si gún o si kàn ẹbati rẹ̀ mọlẹ ṣinṣin.

27. Li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu, o dubulẹ: li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu: ni ibi ti o gbè wolẹ, nibẹ̀ na li o ṣubu kú.

28. Iya Sisera nwò oju-ferese, o si kigbe, o kigbe li oju-ferese ọlọnà pe; Ẽṣe ti kẹkẹ́ rẹ̀ fi pẹ bẹ̃ lati dé? Ẽṣe ti ẹsẹ̀ kẹkẹ̀ rẹ̀ fi duro lẹhin?

29. Awọn obinrin rẹ̀ amoye da a lohùn, ani, on si ti da ara rẹ̀ lohùn pe,

30. Nwọn kò ha ti ri, nwọn kò ha ti pín ikogun bi? fun olukuluku ọkunrin wundia kan tabi meji; fun Sisera ikogun-aṣọ alarabara, ikógun-aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ, aṣọ alarabara oniṣẹ-abẹ́rẹ ni ìha mejeji, li ọrùn awọn ti a kó li ogun.

31. Bẹ̃ni ki o jẹ ki gbogbo awọn ọtá rẹ ki o ṣegbé OLUWA: ṣugbọn jẹ ki awọn ẹniti o fẹ́ ẹ ki o dabi õrùn nigbati o ba yọ ninu agbara rẹ̀. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún.

A. Oni 5