1. NIGBANA ni Debora on Baraki ọmọ Abinoamu kọrin li ọjọ́ na, wipe,
2. Nitori bi awọn olori ti ṣaju ni Israeli, nitori bi awọn enia ti fi tinutinu wá, ẹ fi ibukún fun OLUWA.
3. Ẹ gbọ́, ẹnyin ọba; ẹ feti nyin silẹ, ẹnyin ọmọ alade; emi, ani emi, o kọrin si OLUWA; emi o kọrin iyìn si OLUWA, Ọlọrun Israeli.
4. OLUWA, nigbati iwọ jade kuro ni Seiri, nigbati iwọ nyan jade lati pápa Edomu wá, ilẹ mìtiti, awọn ọrun si kánsilẹ, ani awọsanma pẹlu kán omi silẹ.
5. Awọn òke nla yọ́ niwaju OLUWA, ani Sinai yọ́ niwaju OLUWA; Ọlọrun Israeli.
6. Li ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, li ọjọ́ Jaeli, awọn ọ̀na opópo da, awọn èro si nrìn li ọ̀na ìkọ̀kọ̀.
7. Awọn olori tán ni Israeli, nwọn tán, titi emi Debora fi dide, ti emi dide bi iya ni Israeli.