A. Oni 4:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru li oju OLUWA, nigbati Ehudu kú tán.

2. OLUWA si tà wọn si ọwọ́ Jabini ọba Kenaani, ẹniti o jọba ni Hasori; olori ogun ẹniti iṣe Sisera, ẹniti ngbé Haroṣeti ti awọn orilẹ-ède.

3. Awọn ọmọ Israeli si kigbepè OLUWA: nitoriti o ní ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin; ogun ọdún li o si fi pọ́n awọn ọmọ Israeli loju gidigidi.

4. Ati Debora, wolĩ-obinrin, aya Lappidotu, o ṣe idajọ Israeli li akokò na.

5. On si ngbé abẹ igi-ọpẹ Debora li agbedemeji Rama ati Beti-eli ni ilẹ òke Efraimu: awọn ọmọ Israeli a si ma wá sọdọ rẹ̀ fun idajọ.

6. On si ranṣẹ pè Baraki ọmọ Abinoamu lati Kedeṣi-naftali jade wá, o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun Israeli kò ha ti paṣẹ pe, Lọ sunmọ òke Tabori, ki o si mú ẹgba marun ọkunrin ninu awọn ọmọ Naftali, ati ninu awọn ọmọ Sebuluni pẹlu rẹ.

7. Emi o si fà Sisera, olori ogun Jabini, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati ogun rẹ̀, sọdọ rẹ si odò Kiṣoni; emi o si fi i lé ọ lọwọ.

8. Baraki si wi fun u pe, Bi iwọ o ba bá mi lọ, njẹ emi o lọ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba bá mi lọ, emi ki yio lọ.

9. On si wipe, Ni lilọ emi o bá ọ lọ: ṣugbọn ọlá ọ̀na ti iwọ nlọ nì ki yio jẹ́ tirẹ; nitoriti OLUWA yio tà Sisera si ọwọ́ obinrin. Debora si dide, o si bá Baraki lọ si Kedeṣi.

10. Baraki si pè Sebuluni ati Naftali si Kedeṣi; on si lọ pẹlu ẹgba marun ọkunrin lẹhin rẹ̀: Debora si gòke lọ pẹlu rẹ̀.

A. Oni 4