13. O si kó awọn ọmọ Ammoni ati ti Amaleki mọra rẹ̀; o si lọ o kọlù Israeli, nwọn si gbà ilu ọpẹ.
14. Awọn ọmọ Israeli si sìn Egloni ọba Moabu li ọdún mejidilogun.
15. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn, Ehudu ọmọ Gera, ẹ̀ya Benjamini, ọlọwọ́-òsi: awọn ọmọ Israeli si fi ẹ̀bun rán a si Egloni ọba Moabu.
16. Ehudu si rọ idà kan olojumeji, igbọnwọ kan ni gigùn; on si sán a si abẹ aṣọ rẹ̀ ni itan ọtún.
17. O si mú ọrẹ na wá fun Egloni ọba Moabu; Egloni si jẹ́ ọkunrin ti o sanra pupọ̀.
18. Nigbati o si fi ọrẹ na fun u tán, o rán awọn enia ti o rù ọrẹ na pada lọ.
19. Ṣugbọn on tikara rẹ̀ pada lati ibi ere finfin ti o wà leti Gilgali, o si wipe, Ọba, mo lí ọ̀rọ ìkọkọ kan ibá ọ sọ. On si wipe, Ẹ dakẹ. Gbogbo awọn ẹniti o duro tì i si jade kuro lọdọ rẹ̀.
20. Ehudu si tọ̀ ọ wá; on si nikan joko ninu yará itura rẹ̀. Ehudu si wipe, Mo lí ọ̀rọ kan lati ọdọ Ọlọrun wá fun ọ. On si dide kuro ni ibujoko rẹ̀.
21. Ehudu si nà ọwọ́ òsi rẹ̀, o si yọ idà na kuro ni itan ọtún rẹ̀, o si fi gún u ni ikùn:
22. Ati idà ati ekù si wọle; ọrá si bò idà na nitoriti kò fà idà na yọ kuro ninu ikun rẹ̀; o si yọ lẹhin.