39. Nigbati awọn ọkunrin Israeli si pẹhinda ni ibi ìja na, Benjamini si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn ọkunrin Israeli, o si pa bi ọgbọ̀n enia: nitoriti nwọn wipe, Nitõtọ a lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìja iṣaju.
40. Ṣugbọn nigbati awọsanma bẹ̀rẹsi rú soke lati ilu na wá pẹlu gọ́gọ ẹ̃fi, awọn ara Benjamini wò ẹhin wọn, si kiyesi i, ẹ̃fi gbogbo ilu na gòke lọ si ọrun.
41. Awọn ọkunrin Israeli si yipada, awọn ọkunrin Benjamini si damu: nitoriti nwọn ri pe ibi déba wọn.
42. Nitorina, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọkunrin Israeli si ọ̀na ijù; ṣugbọn ogun na lepa wọn kikan; ati awọn ti o ti ilu wọnni jade wá ni nwọn pa lãrin wọn.
43. Bẹ̃ni nwọn rọgba yi Benjamini ká, nwọn lepa wọn, nwọn tẹ̀ wọn mọlẹ ni ibi isimi, li ọkankan Gibea si ìha ila-õrùn.
44. Ẹgba mẹsan ọkunrin li o si ṣubu ninu awọn enia Benjamini, gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin.
45. Nwọn si yipada nwọn sálọ si ìha ijù sori okuta Rimmoni: nwọn si ṣà ẹgbẹdọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn li opópo; nwọn lepa wọn kikan dé Gidomu, nwọn si pa ẹgba ọkunrin ninu wọn.